Kishore Kumar Hits

Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band - Igbe Apa lyrics

Artist: Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band

album: Olumuyiwa


B'ọmọ bá t'ọkọ ní ò, à fún l'ọkọ
Ṣèbí iyẹn ọmọ t'ó mọ'kọ' lò l'à ńwí
Ọmọ t'á ò kọ', ìyẹn á kó ti'lé tà, pátá-pátá o
B'ó bá wá tà iyẹn tán, á tún bọ' s'óko
Á t'oko, á ta'lẹ, á t'omi, á t'odò
Á ta bàbá, ta yèyé, ta gbogbo ẹbí rẹ' pátá
"Ẹ ò r'áyé wọn l'óde, ọrẹ ò," ni wọn ńké
Ẹ w'ẹ'sín wọn ní'ta, o jàre
"Ẹ ò r'áyé wọn l'óde, awe ò," ni wọn ńké
Ẹ w'ẹ'sín wọn ní'ta, o jàre
Agẹmọ ti bí'mọ rẹ', ó bí'mọ rẹ' sí'nú ẹwà
Àìmọ'ọ'jó ìyẹn wá d'ọwọ ọmọ ò
Ọmọ tí ò gbẹ'kọ', ìyẹn á k'àbámọ ní'wájú o
L'ọjọ ìdààmú, á wá fa'jú roro
A w'òkè, á wo'lẹ, á w'òtún, á w'òsì
A wo bàbá, a wo yèyé, pè gbogbo ẹbí rẹ' s'ẹ'kún
"Ẹ ò r'áyé ún l'óde, ọ'rẹ' ò," l'ó nké
Ẹ w'ẹ'sín ún ní'ta, o jàre
"Ẹ ò r'áyé ún l'óde, àwé ò," l'ó nké
Ẹ w'ẹ'sín ún ní'ta, o jàre

Àṣádànù l'ọmọde ńṣá 'kuta iwájú ilé bàbá rẹ o
Bó bá pẹ', ilé wọn á d'ahoro ò
Ọmọ t'á ò tọ', ìyẹn á kó ti'lé tà pátá-pátá o
B'ó bá wá tà yẹn tán, á tún bọ s'óko
Á t'oko, á ta'lẹ', á t'omi, á t'odò
Á ta bàbá, ta yèyé, ta gbogbo ẹbí rẹ pátá
"Ẹ ò r'áyé wọn l'óde, ọrẹ ò," ni wọn ńké
Ẹ w'ẹ'sín wọn ní'ta, o jàre
"Ẹ ò r'áyé wọn l'óde, àwé ò," ni wọn ńké
Ẹ wẹ'sín wọn ní'ta, o jàre
(Ẹ jọwọ, ẹ tọ'mọ s'ọnà)
Ẹ ma bà wa tọ wọn o, e tọ wọn
Ẹ jọwọ, ẹ kọ'mọ ní'wà, yea (ẹ jọwọ, ẹ kọ'mọ níwà)
Ẹ ma bà wá kọ wọn o, ẹ kọ wọn o
Ẹ jọwọ, e tọ'mọ sọ'nà, ah (ẹ jọwọ, ẹ tọ'mọ sọ́nà)
Ẹ má bà wá tọ wọn o, ẹ tọ wọn
Ẹ jọwọ, ẹ kọ'wọn ní'wà (ẹ jọwọ, ẹ kọ'mọ níwà)
Ẹ má kọ wọn o, ẹ kọ wọn
Ẹ jọwọ, ẹ tọ wọn sọ'nà ah (ẹ jọwọ, ẹ tọ'mọ sọ'nà)
Ẹ ma bà wa tọ wọn o, ẹ tọ wọn
Ẹ jọwọ, ẹ kọ wọn ní'wà (ẹ jọwọ, ẹ kọ'mọ níwà)
Ẹ'jẹ' a má kọ wọn o, ẹ kọ wọn
Ẹ jọ'wọ', ẹ tọ wọn sọ́nà, ah (ẹ jọwọ, ẹ tọ'mọ sọ'nà)
Àní, ẹ tọ wọn o, ẹ tọ wọn
Ẹ jọwọ, ẹ kọ'mọ ní'wà, yeah (ẹ jọwọ, ẹ kọ'mọ níwà)
Ẹ má bà wá kọ wọn o, ẹ ko wọn
Ẹ jọwọ, ẹ tọ'mọ sọ'nà o (ẹ jọwọ, ẹ tọ'mọ sọ'nà)

Поcмотреть все песни артиста

Other albums by the artist

Similar artists