Kishore Kumar Hits

Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band - For Arike lyrics

Artist: Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band

album: Olumuyiwa


Olólùfẹ' àwa, ọmọ Àríkẹ
Ṣebí'wọ lo l'òní o, a dùn wò
Gbogbo ayé mà mí s'àfẹ'rí rẹ
Jíjó rẹ fún wa ká yọ' mọọ l'óde
Rọra, máa gb'ẹsẹ ní kànkan

Rọra máa gb'ẹsẹ ní kànkan
Oníwàtútù yí, ọmọ ìwúrí
Ṣèbí'wọ lo pè wá jọ, a mà dé o
Ojú rẹ dùn wò, ó ń dá ni l'ọ'rùn
Sùgbọn, iwà rẹ lo fi tàn bí òṣùpá
Ilé rẹ wùn wá o, ká jọ dé'bẹ

Ilé rẹ wùn wá o, ká jọ dé'bẹ'
Ṣa ma ṣe tìrẹ o, ọmọ àrídunnú
Má wo t'àwọn ẹlẹ'gàn agbẹ'yìnṣebi
Òjòwú ayé ọ'tá ìlọsíwájú
N'ọwọ' rẹ s'ókè k'o dì mọ're òní
Olólùfẹ' àwa, Àríkẹ' gẹgẹ

Olólùfẹ' àwa, Àríkẹ' gẹgẹ
Omọ'gbẹ'kọ, arẹwà, adáraníjó
Bó bá s'ọgbọn, o ní yẹn, oò rẹ'wẹ'sì
Iṣẹ' ọwọ' rẹ mà gbé ọ lékè
Inú àwa mà ń dùn láti mọ' ọ
Ìjòkó ẹyẹ rẹ wà l'óde máa bọ

Ìjòkó ẹ'yẹ rẹ wà l'óde-
Gbé'ra n'ílẹ', òní l'ọjọ' iyì rẹ
À dé, à bá ẹ yọ

Olólùfẹ àwa, ọmọ Àríkẹ
Ṣebí'wọ lo l'òní o, a dùn wò
Gbogbo ayé mà mí s'àfẹ'rí rẹ
Jíjó rẹ fún wa ká yọ' mọ' ọ l'óde
Rọra máa gb'ẹ'sẹ' ní kànkan

Rọra máa gb'ẹ'sẹ' ní kànkan
Omọ'gbẹ'kọ', arẹwà, adáraníjó
Bó bá s'ọgbọn, o ní yẹn, oò rẹ'wẹ'sì
Iṣẹ' ọwọ' rẹ mà gbé ọ lékè
Inú àwa mà ń dùn láti mọ' ọ
Ìjòkó ẹ'yẹ rẹ wà l'óde, máa bọ'

Ìjòkó ẹ'yẹ rẹ wà l'óde, máa bọ
Ìjòkó ẹ'yẹ rẹ wà l'óde, máa bọ
Ìjòkó ẹ'yẹ rẹ wà l'óde-
Gbé'ra n'ílẹ', òní l'ọjọ' iyì rẹ
À dé, a bá ẹ yọ'

À dé, a bá ẹ yọ' (a dé, a bá ẹ yọ')
Ẹgbẹ Aládùn Onílé, a ba ẹ yọ (a dé, a bá ẹ yọ') a dé, a bá ẹ yọ
À dé, a bá ẹ yọ' (a dé, a bá ẹ yọ')
Ẹgbẹ Aládùn Onílé, a ba ẹ yọ (a dé, a bá ẹ yọ') a dé, a bá ẹ yọ
À dé, a bá ẹ yọ' (a dé, a bá ẹ yọ')
Ẹgbẹ Aládùn Onílé, a ba ẹ yọ (a dé, a bá ẹ yọ') a dé, a bá ẹ yọ'
À dé, a bá ẹ yọ' (a dé, a bá ẹ yọ')
Ẹgbẹ Aládùn Onílé, a ba ẹ yọ (a dé, a bá ẹ yọ') a dé, a bá ẹ yọ'
À dé, a bá ẹ yọ' (a dé, a bá ẹ yọ')

Поcмотреть все песни артиста

Other albums by the artist

Similar artists