Kishore Kumar Hits

Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band - B'o Se Nd'agba lyrics

Artist: Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band

album: Táabákú

Bí'nú rẹ bá dùn k'o rọra ṣe
L'ọ'jọ' ìkorò má fa'jú ro
Kò sí b'ọ'nà ṣe gbòrò tó, gbángungbàngun díẹ' yí ó wà níbẹ' o
Bo r'ẹ'ni nyọ' k'o bá wọn ṣe, ẹni ń sunkún ò, fà wọn mọ'ra
Àní b'o ṣe ń d'àgbà, ọmọ, má ṣe k'ẹ'gbẹ' olókùnkùn
M'ọ'wọ' rẹ s'óun rere ṣe
Mo ní b'o ṣe ń g'òkè ìlérí, má gbàgbé ìbẹ'rẹ'
M'ọ'wọ' rẹ s'óun réré ṣe

B'o l'ọ'rọ' púpọ' má fi ṣ'akọ, bí ò sí o, má ṣè'lara
Kò sí b'ọ'nà ṣe gbòrò tó, gbángungbàngun díẹ' yí ó wà níbẹ' o
Àríyọ' mi ò, ọmọ rere, ìtùnú òbí rẹ' l'ọ'jọ' ogbó
Àní b'o ṣe ń d'àgbà, ọmọ Akin, má ro'jú, má ṣ'ọ'le
M'ọ'wọ' rẹ s'óun réré ṣe
Mo ní b'ẹ ṣe ń d'àgbà, ọmọ, má ṣe kún wọn ní'gbìmọ' ọ'tẹ'
M'ọ'wọ' rẹ s'óun réré ṣe
Moní b'o ṣe ń làkàkà, ọmọ, má ro'jú, má ṣ'ọ'le
M'ọ'wọ' rẹ s'óun rere ṣe
Kò sí b'ọ'nà ṣe gbòrò tó, gbángungbàngun díẹ' yí ó wà níbẹ' o
Àní b'o ṣe ń d'àgbà, ọmọ, má ṣe k'ẹ'gbẹ' olókùnkùn
M'ọ'wọ' rẹ s'óun réré ṣe
Mo ní b'o ṣe ń g'òkè ìlérí, má gbàgbé ìbẹ'rẹ'
M'ọ'wọ' rẹ s'óun réré ṣe

Поcмотреть все песни артиста

Other albums by the artist

Similar artists