Kishore Kumar Hits

Bode Afolabi - Jesu Oro Re Ye lyrics

Artist: Bode Afolabi

album: Yoruba Most Loved Hymns Vol. 1


Jesu, oro Re ye,
O si nto 'sise wa;
Enit' o ba gbagbo,
Y' o layo on 'mole.
Nigb' ota sunmo wa,
Oro Re l'odi wa;
Oro itunu ni,
Iko igbala ni.
B'igbi at' okunkun
Tile bow a mole;
'Mole re y'o to wa,
Y'o si dabobo wa.
Tani le so ayo,
T'o le ka isura,
Ti oro Re nfi fun
Okan onirele?
Oro anu, o nfi
'Lera fun alaye,
Oro iye, o nfi
Itunu f'eni nku.
Awa iba le mo
Eko ti o nkoni,
Ki a ba le fe O,
K' a si le sunmo O.

Поcмотреть все песни артиста

Other albums by the artist

Similar artists